1. OLUWA wow a l’ ese Re
Otosi elese;
Gege bi eniti nbebe,
A wa ni ase Re.
2. A wa mbebe f’ awon ‘mo wa,
T’ Iwo ti fi fun wa;
Tal’ a o to n’ igba aini?
Bikose odo Re.
3. A ko bere oro fun won,
N’ ijakadi aiye;
Sugbon l’ oruko Jesu nla
A mbebe fun iye.
4. A wa nfe Emi isoji,
K’ O tun okan won se,
Ki nwon le wa niwaju Re,
Ki nwon le r’ ogo Re.
(Visited 201 times, 1 visits today)