YBH 94

WO! gbogbo ile okunkun

1. WO! gbogbo ile okunkun,
Wo! okan mi, duro je;
Gbogbo ileri ni o nso
T’ ojo ayo t’o l’ ogo;
Ojo Ayo!
K’ owuro re yara de!

2. Ki India on Afrika,
K’ alaigbede gbogbo ri
Isegun nla t’ o l’ ogo ni,
T’ ori oke Kalfari:
K’ ihinrere
Tan lat’ ilu de ilu.

3. Ijoba t’ o wa l’ okunkun,
Jesu, tan ‘mole fun won.
Lat’ ila-orun de ‘wo re,
K’ imole le okun lo;
K’ irapada
Ti a gba l’ ofe bori.

4. Ma tan lo, ‘wo ihinrere,
Ma segun lo, ma duro:
K’ ijoba re aiyeraiye
Ma bi si, k’ o si ma re;
Olugbala
Wa, joba gbogbo aiye.

(Visited 357 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you