YBH 93

OJO ayo nlanla na de

1. OJO ayo nlanla na de,
Eyit’ araiye ti nreti;
Nigbat’ Olugbala w’ aiye,
Nigbat’ a bi ninu ara.

2. Olusagutan ni papa,
Bi nwon ti nso agutan won,
Ni ihin ayo na ko ba:
Ihin bibi Olugbala.

3. Agel’ iranse Oluwa;
L’ a ran si won alabukun,
Pelu ogo t’ o tan julo,
Lati so ihin ayo yi.

4. Gidigidi l’ eru ba won,
Fun ajeji iran nla yi;
“Ma beru” l’ oro iyanju
T’ o t’ enu Angeli na wa.

5. A bi Olugbala loni,
Kristi Oluwa aiye ni;
N’ ilu nla Dafidi l’ o wa,
N’ ibuje eran l’ a te si.

6. “Ogo fun Olorun” l’ orin
Ti enia y’ o ko s’ orun;
Fun ife Re ti ko l’ opin,
T’ o mu Alafia w’ aiye.

(Visited 535 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you