YBH 97

ONIGBAGBO, e bu s’ ayo

1. ONIGBAGBO, e bu s’ ayo!
Ojo nla l’ eyi fun wa;
K’ orun f’ ayo korin kikan,
K’ igbo at’ odan gberin.
E ho! ! e yo!
Okun at’ odo gbogbo.

2. E jumo, yo, gbogbo eda,
L’ aiye yi ati l’ orun;
Ki gbogbo ohun alaye
N’ ile, l’ oke, yin Jesu.
E f’ ogo fun
Oba nla t’ a bi loni.

3. Gb’ ohun yin ga, “Om’ Afrika”
Enyin iran Yoruba;
Ke “Hosanna” l’ ohun goro
Jake-jado ile wa.
K’ oba gbogbo,
Juba Jesu Oba wa.

4. E damuso! e damuso!
E ho ye! k’ e si ma yo;
Itegun Esu fo wayi,
“Iru-omobirin” de.
Halleluya!
Olurapada, Oba

5. E gb’ ohun nyin ga, Serafu,
Kerubu, leba ite;
Angeli at’ enyin mimo,
Pelu gbogb’ ogun orun,
E ba way o!
Odun idasile de.

6. Metalokan, Eni Mimo
Baba Olodumare,
Emi Mimo, Olutunu,
Jesu, Olurapada,
Gba iyin wa
‘Wo nikan l’ ogo ye fun.

(Visited 3,650 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you