1. AYO kun okan wa loni
A bi Omo Oba;
Opo awon ogun orun,
Nso t’ ibi Re loni:
E yo, Olorun d’ enia,
O wa joko l’ aiye,
Oruko wo l’o dun to yi –
Emmanuel.
2. A wole n’ ibuje eran,
N’ iyanu l’ a josin:
Ibukun kan ko ta yi yo,
Ko s’ ayo bi eyi:
3. Aiye ko n’ adun fun wa mo,
‘Gbati a ba nwo O;
L’ owo Wundia iya Re
‘Wo Omo iyanu.
4. Imole lat’ inu ‘Mole,
Tan ‘mole s’ okun wa,
K’ a le ma fi isin mimo
Se ‘ranti ojo Re.
(Visited 1,188 times, 1 visits today)