Yoruba Baptist Hymns
BABA, a tun pade l’ oko Jesu
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
BABA, a tun pade l’ oko Jesu,
A si wa teriba lab’ ese Re;
Si O l’ a tun fe gb’ ohun wa s’ oke
Lati wa anu, lati ko ‘rin ‘yin.
Verse 2
A yin O fun itoju ‘gbagbogbo,
‘Jojumo l’ a o ma so t’ ise Re:
Wiwa l’aiye wa, anu Re ha ko?
Apa Re ki O si fi ngba ni mora?
Verse 3
O se! a ko ye fun ife nla Re,
A sako kuro lodo Re poju:
Sugbon kikankikan ni O si npe;
Nje, a de, a pada wa ‘le, Baba.
Verse 4
Nipa oko t’ o bor’ ohun gbogbo,
Nipa ife t’ o ta ‘fe gbogbo yo,
Nipa eje ti a ta fun ese,
S’ ilekun anu, si gbani s’ ile.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/baba-a-tun-pade-l-oko-jesu/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.