IWO imole okan mi
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
IWO imole okan mi,
Li odo Re oru ko si,
Ki kuku aiye ma bo O
Kuro l’ oju iranse Re.
Verse 2
Nigbat’ orun ale didun
Ba npa ipenpeju mi de,
K’ ero mi je lati simi
Lai, l’aiya Olugbala mi.
Verse 3
Ba mi gbe l’ oro tit’ ale
Laisi Re, emi ko le wa;
Ba mi gbe gbat’ ile ba nsu.
Laisi Re, emi ko le ku.
Verse 4
B’ awon otosi omo Re
Ta ‘pa si oro Re l’ oni,
Oluwa sise ore Re,
Ma je k’ a joko si ese.
Verse 5
Bukun fun awon alaisan,
Ninu opo ibukun Re;
K’ orun alawe l’ale yi,
Dabi orun omo titun.
Verse 6
Sure fun wa nigbat’ a ji,
K’ a to m’ ohun aiye yi se.
Titi awa o de b’ ife
T’a o si de ijoba Re.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.