Yoruba Baptist Hymns
OJISE Krist’, dide
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
OJISE Krist’, dide,
E mura fun ‘se na,
Iri ‘bukun lat’ orun wa
Ti se s’ ori ile.
Verse 2
Lo toju alaisan,
At’ awon ti nsofo,
Lo s’ odo awon ti nronu,
K’ o si tu won ninu.
Verse 3
F’ itara se ‘ranwo
Fun awon elese,
Nibit’ ijo mimo nkunle,
T’ olukoni pe si.
Verse 4
Fa ‘gbagbo ti nf’ oju
Adua w’ oke mora,
Si f’ ife ti ki yipada,
Ti Jesu bo ‘ra re.
Verse 5
Gbana ‘wo o pin n’nu
Oro ti ki baje,
‘Bukun t’ o wa n’nu ‘hinrere,
Yio san lala re.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/ojise-krist-dide/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.