TAL’ awon wonyi b’ iranwo,
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
TAL’ awon wonyi b’ iranwo,
Niwaju ‘te Olorun?
Gbogbo nwon de ade wura,
Egbe ogo wo l’ eyi?
Gbo! nwon nko, Alleluya,
Nwon nf’ iyin fun Oba won,
Verse 2
Tali awon ti nko mona,
T’ a wo l’ aso ododo;
Awon ti aso funfun won,
Y’o wa ni mimo titi,
Ti ki o si gbo lailai?
Nibo l’ egbe yi ti wa?
Verse 3
Awon wonyi l’ o ti jagun,
F’ ola Olugbala won,
Nwon ja titi d’ oju iku,
Nwon ko k’ egbe elese;
Awon ni ko sa f’ ogun,
Nwon segun nipa Kristi.
Verse 4
Awon yi l’ okan won gbogbe,
Ninu ‘danwo kikoro,
Awon l’ o ti fi adura
B’ Olorun jijakadi;
‘Rora ija won pari,
Olorun re won l’ ekun
Verse 5
Awon wonyi l’ o ti sona,
Nwon f’ ife won fun Kristi,
Nwon si ya ‘ra won si mmo,
Lati sin nigbagbogbo;
Nisisiyi li orun,
Nwon wa l’ ayo l’ odo Re.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.