YBH 100

ENYIN Angel’ l’ orun ogo

1. ENYIN Angel’ l’ orun ogo
To yi gbogbo aiye ka,
E ti ko ‘rin dida aiye,
E so t’ ibi Messia,
E wa josin
Fun Kristi Oba titun.

2. Enyin Oluso-agutan,
Ti nso eran nyin l’ oru,
Emanuel wa ti de
Iranwo Omo na ntan,

3. Onigbagbo ti nteriba,
Ni ‘beru at’ ireti,
L’ ojiji l’ Oluwa y’o de,
Ti yio mu nyin re ‘le

4. Elese, ‘wo alaironu,
Elebi ati egbe,
Ododo Olorun duro,
Anu npe o, pa wad a,

5. Gbogbo eda e fo f’ ayo,
Jesu Olugbala de;
Anfani miran ko si mo,
B’ eyi ba fo nyin koja,
Nje e wa sin,
Sin Kristi Oba Ogo.

(Visited 1,146 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you