1. GBO ohun alore,
Ji, ara, ji:
Jesu ma fere, de,
Ji, ara, ji
Omo oru ni sun,
Omo imole l’ enyin,
Ti nyin l’ ogo didan,
Ji, ara, ji.
2. So f’ egbe t’ o TI JI,
Ara, sora;
Ase Jesu daju,
Ara, sora;
E se b’ olusona
N’ ilekun Oluwa nyin,
Bi o tile pe de,
Ara, sora.
3. Gbo ohun Iriju,
Ara, sise;
Ise na kari wa,
Ara, sise;
Ogba Oluwa wa,
Kun fun se nigbagbogbo
Y’o si fun wa l’ ere,
Ara, sise.
4. Gb’ ohun Oluwa wa,
E gbadura;
B’ e fe k’ inu Re dun
E gbadura;
Ese mu ‘beru wa,
Alailera si ni wa;
Ni ijakadi nyin,
E gbadura.
5. Ko orin ikehin,
Yin, ara, yin;
Mimo ni Oluwa,
Yin, ara, yin;
Kil’ o tun ye ahon,
T’o fere b’ Angel’ korin,
T’ y’o ro l’ orun titi,
Yin, ara, yin.
(Visited 726 times, 1 visits today)