1. JI, ‘wo Kristian, k’ o ki oro ayo
Ti a bi Olugbala araiye;
Dide, k’ o korin ife Olorun,
T’ awon Angeli nko n’ ijo kini,
Lat’ odo won n’ ihin na ti bere;
Ihin Om’ Olorun t’ a bi s’ aiye.
2. ‘Gbana l’ a ran akede Angeli,
T’o so f’ awon Olusagutan, pe,
“mo mu ‘hin rere Olugbala wa,
T’a bi fun nyin ati gbogbo aiye.”
Olorun mu ‘leri Re se loni,
A bi Olugbala, Krist’ Oluwa.
3. Bi akede Angel’ na ti so tan,
Opolopo ogun orun si de;
Nwon nkorin ayo t’ eti ko gbo ri,
Orun si ho fun ‘yin Olorun pe,
“Ogo ni f’ Olorun l’ oke orun
Alafia at’ ife s’ enia.”
4. O ye k’ awa k’ o ma ro l’ okan wa,
Ife nla t’ Olorun ni s’ okan wa,
K’ a sir o t’ omo na t’ a bi loni,
T’ o wa jiya oro agbelebu.
Ki awa si tele liana Re,
Titi a o fi de ‘bugbe l’oke.
5. Nigbana ‘gba ba de orun lohun,
A o korin ayo t’ irapada;
Ogo Enit’ a bi fun wa loni,
Y’o ma ran yi wa ka titi lailai;
A o ma korin ife Re titi,
Oba Angeli, Oba enia.