1. N’NU ‘se, n’nu ‘ja, Oluwa mi,
Ngo rin li ona Re;
B’ Iwo ti se l’ emi o se,
Nipa iranwo Re.
2. Pelu ‘tara, ayo l’o fi
Se ife Baba Re;
Itara na ‘ ba le mu mi
Lati m’ ofin Re se.
3. Iwa pele, oto, ife
Nhan n’ iwa Re gbogbo;
A! gbogbo ‘se mi, Oluwa
‘Ba je le je Tire.
(Visited 172 times, 1 visits today)