1. JESU, O ha re ‘ra Re le
Gbat’ O gb’ ara wa wo?
Lati se awotan aisan,
Lati l’ arun jade?
2. O ha te ‘ti si alagbe,
O m’ afoju riran?
Gbo, Omo dafidi, a! gbo,
Sanu fun mi pelu.
3. O ha kanu fun ‘se eda,
O tun mu ‘lera wa?
Oluwa jo gb’ okan mi la,
T’ o nfe anu Re ju.
4. O ha y’ Omo-do t’ o mberu
Gbat’ o nri n’nu igbi?
Oluwa gb’ okan mi, mo gbe;
Iwo l’o le gbala.
(Visited 154 times, 1 visits today)