YBH 108

OPARI! – l’ Olugbala ke

1. OPARI! – l’ Olugbala ke,
O te ori ba, O si ku;
“O pari!” – ire – ije pin,
O ti jagun, O si segun.

2. “O pari!” – igbe iku yi
Y’o s’ etutu f’ ese gbogbo,
Opo y’o si ri igbala
Nipa emi ‘kehin Jesu.

3. “O pari!” – a b’ orun la ‘ja
A ba ipa okunkun je;
Alafia, ife at’ ayo
Pada wa ba elese gbe.

4. “O pari!” – k’ iro ayo yi
Ka gbogbo orile-ede;
“O pari!” – k’ isegun na nde
Ko dapo mo orin t’ oke.

(Visited 293 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you