YBH 110

MO f’ ara Mi fun o

1. MO f’ ara Mi fun o,
Mo ku nitori re,
Ki nle ra o pada,
K’ o le jinde n’nu ‘ oku;
Mo f’ ara Mi fun o,
Kin’ iwo se fun Mi?

2. Mo f’ ojo aiye Mi
Se ‘se lala fun o;
Ki iwo ba le mo
Adun aiyeraiye
Mo se lala fun o
Kin ‘ iwo se fun Mi?

3. Ile ti Baba Mi,
At’ ite ogo Mi,
Mo fi sile w’ aiye,
Mo d’ alarinkiri,
Mo fi ‘le tori re
Kil’ o fi ‘le fun Mi?

4. Mo jiya po fun o,
Ti enu ko le so
Mo j’ ijakadi nla,
‘Tori igbala re;
Mo jiya po fun o,
O le jiya fun Mi?

5. Mo mu igbala nla,
Lat’ ile Baba Mi
Wa, lati fifun o,
Mo si dariji o:
Mo m’ ebun wa fun o,
Kil’ o mu wa fun Mi?

6. Fi ara re fun Mi,
Fi aiye re sin Mi,
Di ‘ju si kan t’ aiye,
Si wo ohun t’ orun,
Mo f’ ara Mi fun o,
Si f’ ara re funMi.

(Visited 8,388 times, 2 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you