1. A RA, e wa ba mi s’ ofo,
E wa sodo Olugbala;
Wa, e je k’ a jumo s’ ofo;
A kan Jesu m’ agbelebu.
2. ko ha s’ omije loju wa
bi awon Ju ti nfi sefe?
A! E wo, b’ O ti teriba;
A kan Jesu m’ agbelebu.
3. Emeje l’ o soro ife;
Idake wakati meta
L’ O fi ntoro anu f’ anu;
A kan Jesu m’ agbelebu.
4. Bu s’ ekun, okan lile mi!
Ese at’ igberaga re
L’ o da Oluwa re l’ ebi;
A kan Jesu m’ agbelebu.
5. Wa duro ti agbelebu,
K’ eje tin jade n’ iha Re
Ba le ma san le o lori;
A kan Jesu m’ agbelebu.
6. Ibanuje at’ omije,
Bere, a ki o fi du o;
‘Banuje l’ o f’ ife re han
A kan Jesu m’ agbelebu.
7. Ife Baba, ese eda,
Nihin l’ a ri agbara re;
Ife l’ o si di Asegun;
A kan Olufe wa mo ‘gi
(Visited 377 times, 1 visits today)