1. EGB’ ohun ife at’ anu,
Ti ndun l’ oke Kalfari!
Wo! O san awon apata!
O mi ‘le, o m’ orun su!
“O ti pari!”
Gbo b’ Olugbala ti ke.
2. O ti pari!” B’ o ti dun to,
Ohun t’ oro wonyi wi,
Ibukun orun l’ ainiye
T’ odo Kristi san si wa.
“O ti pari!”
E ranti oro wonyi.
3. Ise igbala wa pari,
Jesu ti mu ofin se;
O pari nkan t’ Olorun wi,
Awa ki y’o ka ‘ku si.
“O ti pari!”
Elese, ipe l’ eyi
4. E tun harpu nyin se, Seraf’,
Lati korin ogo Re;,
Ar’ aiye at’ ara orun,
Yin ‘ruko Emmanuel.’
“O ti pari!”
Ogo fun Od’ agutan.
(Visited 336 times, 1 visits today)