1. OLUGBALA mi ha gb’ ogbe?
K’ Oba Ogo si ku?
On ha je f’ ara Re rubo
F’ eni ile b’ emi?
2. Iha se ese ti mo da
L’ o gbe ko sor’ igi?
Anu at’ ore yi ma po,
Ife yi rekoja!
3. O ye k’ orun f’ oju pamo,
K’ o b’ ogo re mole;
Gbati Kristi Eleda ku,
Fun ese eda Re.
4. Be l’ o ye k’ oju ba ti mi
‘Gba mo r’ agbelebu;
O ye k’ okan mi kun f’ ope,
O ju mi f’ omije.
5. Sugbon omije ko le san
‘Gbese ‘fe ti mo je;
Mo f’ ara mi f’ Oluwa mi
Eyi lo ye kin se.
(Visited 576 times, 1 visits today)