1. GBO-GB’ ogo iyin ola,
Fun O oludande,
S’ Eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun!
‘Wo l’ Oba Israeli,
Om’ Alade Dafidi,
T’ O wa l’ Oko Oluwa,
Oba olubukun.
Gbogb’ ogo iyin ola
Fun O, Oludande,
S’ Eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun!
2. Egbe awon maleka,
Nyin O l’ oke giga;
Awa at’ eda gbogbo
Si dapo gberin na.
3. Awon Hebru lo, saju,
Pelu imo ope,
Iyin, adura, at’ orin,
L’ a mu wa ‘waju Re.
4. Si O saju iya Re,
Nwon korin iyin won;
‘Wo t’a gbega nisiyi,
L’ a nkorin iyin si.
5. ‘Wo gba orin iyin won:
Gb’ adura t’a mu wa,
‘Wo ti nyo s’ ohun rere,
Oba wa Olore.
(Visited 974 times, 2 visits today)