YBH 116

WO t’ o nbebe f’ ota Re

1. WO t’ o nbebe f’ ota Re,
L’ or’ igi agbelebu;
Wipe “Fiji won Baba”,
Jesu sanu fun wa.

2. Jesu jo bebe fun wa,
Fun ese wa gbagbogbo;
A ko mo ohun t a nse
Jesu sanu fun wa.

3. Je k’ awa ti nwa anu,
Dabi Re l’ okan n’ iwa,
‘Gba t’ a ba se wa n’ ibi:
Jesu sanu fun wa.

4. Jesu ‘Wo t’ o gbo aro
Ole t’ o ku l’ egbe Re,
T’ O si mu d’ orun rere:
Jesu sanu fun wa.

5. Ninu ebi ese wa,
Je k’ a toro anu Re,
K’ a ma pe oruko Re,
Jesu sanu fun wa.

6. Ranti awa ti nrahun
T’ a now agbelebu Re;
F’ ireti mimo fun wa
Jesu sanu fun wa.

7. ‘Wo t’ o fe l’afe dopin
Iya Re t’ o nkanu Re,
Ati ore Re owon:
Jesu sanu fun wa.

8. Je k’ a pin ‘nu iya Re,
K’ a ma ko iku fun O,
Je k’ a ri ‘toju Re gba;
Jesu sanu fun wa.

9. Ki gbogbo awa tire,
Je omo ile kanna,
“Tori Re k’a fe ‘ra wa:
Jesu sanu fun wa.

10. Jesu ‘Wo ti eru nba,
‘Gbat’ osi ‘Wo nikan,
Ti okunkun su bo O:
Jesu sanu fun wa.

11. ‘Gbati a ba npe lasan,
T’ ireti wa si jina;
N’nu okun na di wa mu
Jesu sanu fun wa.

12. B’ o dabi Baba ko gbo,
B’ o dabi ‘mole ko si,
Je ka fi ‘gbagbo ri O,
Jesu sanu fun wa.

13. Jesu ninu ongbe Re,
Ni ori agbelebu,
‘Wo ti o few a sibe;
Jesu sanu fun wa.

14. Ma kongbe ife Re
Sise mimo lara wa,
Te ife Re na l’ orun
Jesu sanu fun wa.

15. Je k’ a kongbe ife Re
Ma samona wa titi,
Sibi omi iye ni;
Jesu sanu fun wa.

16. Jesu Olurapada,
‘Wo t’ o se ‘fe Baba Re,
T’o si jiya ‘tori wa;
Jesu sanu fun wa.

17. Gba wa l’ ojo idamu,
Se oluranlowo wa,
Lati ma t’ ona mimo;
Jesu sanu fun wa.

18. F’ imole Re s’ ona wa,
Ti v’ o ma tan titi lai,
Tit’ ao fi de odo Re:
Jesu sanu fun wa.

19. Jesu gbogbo ise Re,
Gbogbo Damu Re pin,
O Jowo emi Re lowo;
Jesu sanu fun wa.

20. ‘Gbat’ iku ba de ba wa,
Gba wa lowo ota wa;
Yo wa ni wakati na,
Jesu sanu fun wa.

21. Ki iku at’ iye Re,
Mu ore ofe ba wa,
Ti yio, mu wa d’oke:
Jesu sanu fun wa.

(Visited 1,847 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you