1. MA gesin lo l’ olanla Re;
Gbo, gbogb’ aiye nke “Hosanna”,
Olugbala ma lo pele
Lori ‘m’ ope at aso.
2. Ma gesin lo l’ olanla Re;
Ma f’ irele gesin, lo ku:
Kristi ‘segun Re bere na,
Lori ese ati iku.
3. Ma gesin lo l’ olanla Re:
Ogun angeli lat’ orun
Nf’ iyanu pelu ikanu,
Wo ebo to sunmole yi.
4. Ma gesin lo l’ olanla Re,
Ija ikehin na de tan;
Baba lor’ ite Re l’ orun
Nreti ayanfe omo Re.
5. Ma gesin lo l’ olanla Re.
Ma f’ irele gesin lo ku,
F’ arada irora f’ eda:
Lehin na nde k’ o ma joba.
(Visited 2,738 times, 1 visits today)