YBH 118

KRIST’ Oluwa ji loni, – Halleluyah

1. KRIST’ Oluwa ji loni, – Halleluyah,
Eda at’ Angeli nwi – Hal.
Gb’ ayo at’ isegun ga – Hal.
K’ orun at’ aiye gberin! – Hal.

2. Ise ti idande tan; – Hal.
O jija, O ti segun; – Hal.
Wo, ‘ponju orun koja – Hal.
Ko wo sinu eje mo – Hal.

3. Lasan n’ iso at’ ami, – Hal.
Krist’ woo run apadi; – Hal
Lasan l’ agbara iku, – Hal.
Krist, si Paradise. – Hal.

4. O tun wa, Oba ogo: – Hal.
“Iku itani re wa?” – Hal.
Lekan l’ O ku k’ O gba wa, – Hal.
“‘Boji, isegun re wa?” – Hal.

5. E je k’ awa goke lo, – Hal.
Sodo Kristi Ori wa, – Hal.
A sa jinde pelu Re, – Hal.
Bi a ti ku pelu Re. – Hal.

6. Oluwa t’ aiye t’ orun, – Hal.
Tire ni gbogbo iyin, – Hal.
A wole niwaju Re – Hal.
‘Wo Ajinde at’ Iye. – Hal.

(Visited 1,734 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you