1. “OLUWA ji loto:”
O wa ko ni ku mo,
O wa lati be f’ elese,
Ti o ru egan won.
2. “Oluwa ji loto:”
Esu so tire nu:
Awon t’ a ra ji pelu Re,
Lati joba lailai.
3. “Oluwa ji loto:”
Enyin Angeli gbo:
S’ agbala orun e sare
Mu ‘hin ayo na lo.
4. E mu duru wura,
K’ e si te ‘rin didun:
Enyin egbe orun dapo,
Lati k’ ajinde Re.
(Visited 385 times, 1 visits today)