1. KABO ojo rere, ” l’ ao ma wi titi;
A sete ‘ku loni, orun di tiwa.
‘Wo oku d’ alaye, oba tit’ aiye,
Gbogb’ eda Re, Jesu, ni nwon njuba Re.
“Kabo ojo rere,” l’ ao ma wi titi,
A sete ‘ku loni, orun di tiwa.
2. Eleda, Oluwa, Emi alaye!
Lat’ orun l’ O ti bojuwo ‘sina wa;
Om’ Olorun papa n’ Iwo tile se,
K’ O ba le gba wa la, O di enia.
3. ‘Wo’ Olorun iye, O wa to ‘ku wo:
Lati f’ ipa Re han, O sun n’ iboji,
Wa, Eni Oloto, si m’ oro Re se,
Ojo ‘keta Re de, jinde Oluwa.
4. Tu ibekun sile, t’ Esu de l’ ewon,
Awon t’ o si subu, jog be won dide,
F’ ojurere Re han, je k’ aiye riran,
Tun mu ‘mole wa de, ‘ wo sa ni ‘mole.
(Visited 1,365 times, 1 visits today)