YBH 123

ALLELUYA! Alleluya!! Alleluya!!!

1. ALLELUYA! Alleluya!! Alleluya!!!
Ija d’ opin, ogun si tan:
Olugbala jagun molu:
Orin ayo l’ a o ma ko. Alleluya!

2. Gbogbo ipa n’ iku si lo:
Sugbon Kristi f’ ogun re ka:
Aiye E ho iho ayo – Alleluya!

3. Ojo meta na ti koja.
O jinde kuro nin’ oku:
E f’ ogo fun Olorun wa. – Alleluya!

4. O d’ ewon orun apadi,
O s’ ilekun orun sile:
E korin iyin ‘segun Re. – Alleluya!

5. Jesu nipa iya t’ O je,
A bo lowo iku titi:
Titi l’ a o si ma yin O. – Alleluya!

(Visited 3,084 times, 2 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you