YBH 124

HALLELUYAH, Halleluyah

1. HALLELUYAH, Halleluyah,
E gbe ohun ayo ga,
E korin inudidun,
K’ e si yin olorun wa,
Enit’a kan m’agbelebu,
T’ o jiya fun ese wa;
Jesu Kristi Oba ogo
Jinde kuro n’nu oku.

2. Irin idabu se kuro
Kristi ku, O sit un ye,
O mu iye at aiku
Wa l’oro ajinde Re;
Krist’ ti’ segun, awa segun
Nipa agbara nla Re,
Awa o jinde pelu Re,
A o ba wo ‘nu ogo.

3. Kristi jinde, akobi ni
Ninu awon t’ o ti sun,
Awon yi ni y’ o ji dide,
Ni abo Re ekeji;
Ikore ti won ti pon tan
Nwon nreti Olukore,
Eniti y’o mu won kuro,
Ninu isa oku won.

4. Awa jinde pelu Kristi
T’O nfun wa l’ ohun gbogbo
Ojo, iri, ati ogo
To ntan jade l’ oju Re;
Oluwa b’ a ti wa l’aiye,
Fa okan wa s’odo Re,
K’awon maleka saw a jo,
Ki nwon ko wa d,odo Re.

5. Halleluyah, Halleluyah!
Ogo ni fun Olorun;
Halleluyah f’ Olugbala
Enit’ Osegun iku.
Halleluyah f’ Emi Mimo,
Orison ‘fe, ‘wa mimo,
Halleluyah, Halleluyah,
F’ Olorun Metalokan.

(Visited 707 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you