1. JESU ye; titi aiye
Eru iku ko ba ni mo;
Jesu ye; nitorina
Isa oku ko n ‘ipa mo. – Alleluya!
2. Jesu ye; lat’ oni lo
Iku je ona si iye;
Eyi y’o je ‘ tunu wa
‘Gbat’ akoko iku ba de. – Alleluya!
3. Jesu ye; fun wa l’ O ku;
Nje Tire ni a o ma se;
A o f’okan funfun sin,
A o f’ogo f’Olugbala. – Alleluya!
4. Jesu ye; eyi daju,
Iku at’ ipa okunkun
Ki y’o le ya ni kuro
Ninu ife nla ti Jesu. – Alleluya!
5. Jesu ye; gbogbo ‘joba
L’orun, li aiye, di Tire;
E ja ki a ma tele
Ki a le joba pelu Re. – Alleluya.
(Visited 6,382 times, 1 visits today)