1. OLUWA mbo aiye o mi
Oke y’o sidi n’ipo won;
At ‘irawo oju orun,
Y’o mu imole won kuro.
2. Oluwa mbo; bakanna ko;
Bi o ti wa n’ irele ri,
Odo agutan ti a pa,
Eni iya ti o si ku.
3. Oluwa mbo; li eru nla,
L’Owo ina pelu ija
L’or ‘iye apa kerubu,
Mbo Onidajo Araiye.
4. Eyi ha li eniti nrin,
Bi ero l’opopo aiye
Ti a se ‘nunibinu si
A! Eniti a pa l’eyi.
5. Ika; b’e wo ‘nu apata,
B’e wo ‘nu iho lasan ni;
Sugbon igbagbo t’o segun,
Y’o korin pe, Oluwa de.
(Visited 812 times, 1 visits today)