YBH 127

OLORUN! Kini mo ri yi

1. OLORUN! Kini mo ri yi!
Opin de f’ohun gbogbo!
Onidajo araiye yo,
O gunwa n’ite ‘dajo
Ipe dun, iboji sit u,
Gbogbo awon oku sile;
Mura, lo ko okan mi.

2. Oku ‘nu Kristi y’o ko jinde,
Nigba ‘pe kehin ba dun,
Nwon o lo ko l’awosanna,
Nwon o fi ayo yi ka;
Ko s’eru ti y’o b’okan won
Oju Re da imole bo,
Awon ti o mura de.

3. Sugbon elese t’on t’eru,
Ni gbigbona ‘binu Re,
Nwon o dide, nwon o si ri,
Pe, ose won ko ba mo;
Ojo ore-ofe koja;
Nwon ngbon niwaju ‘te ‘dajo,
Awon ti ko mura de.

4. Olorun kini mo ri yi
Opin de f’ohun gbogbo!
Onidajo araiye yo,
O gunwa n’ite ‘dajo
L’ese agbelebu, mo nwo
‘Gbat ‘Ohun gbogbo y’o koja;
Bayi ni mo nmura de.

(Visited 322 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you