1. JESU t’o k’o gb’aiye la,
Jinde kuro ninu oku,
Nipa agbara Re;
A da, sile lowo iku,
O di ‘gbekun n’igbekun lo,
O ye, k’o ma ku mo
2. Enyin om’Olorun, e wo
Olugbala ninu ogo;
O ti segun iku,
Ma banuje, ma beru mo,
O nlo pese aye fun nyin,
Yio mu yin lo ‘le.
3. O f’oju anu at’ife
Wo awon ti O ra pada;
Awon ni ayo Re;
O ri ayo at;ise won,
O bebe kinwon le segun,
Ki nwon ba job alai.
(Visited 257 times, 1 visits today)