1. L’OWURO, Ojo ajinde,
T’ara t’okan y’o pade,
Ekun, ‘kanu on irora
Y’o d’opin.
2. Nihin nwon ko le sai pinya,
Ki ara ba le simi,
K’o si fi idakeroro
Sun fonfon.
3. Fun ‘gba die ara are yi,
L’ gbe s’ibi ‘sinmi re:
Titi di imole oro
Ajinde.
4. Okan t’o kanu nisiyi
To si ngbadura kikan.
Y’o nu s’orin ayo l’ojo
Ajinde.
5. Ara at’okan y’o dapo,
Ipnya ko ni si mo:
Nwon o ji l’aworan Kristi’ni
‘Telorun.
6. A, ewa na at ‘yo na
Y’o ti po to l’Ajinde
Y’o duro b’orun at’aiye
Ba fo lo.
7. L’oro ojo ajinde wa,
‘Boji Y’o m’oku re wa:
Baba, iya, omo, ara
Y’o pade.
8. Si ‘dapo ti o dun bayi,
Jesu ma – sai ka wa ye:
N’nu ‘ku, ‘dajo, k’a le ro ‘m’a
‘Gbelebu.
(Visited 5,389 times, 1 visits today)