YBH 131

ORU bu koja tan

1. ORU bu koja tan
Osan ku si dede:
Iboju fere ya
T’o bo Olugbala;
Sanmi ti odi wa loju
L’a fere tu kakiri na.

2. E gb’ori nyin s’oke,
Igbala sunmo ‘le,
Wo bi orun tin ran,
Oju orun mole;
Enia mimo, e si ma yo;
Oluwa fere f’ara han.

3. Bi enia nrerin yin,
Ti nwon ko fe gbagbo,
Enyin gb’oro Re gbo,
On ko le tan nyin je,
Nigbati aiye ba koja,
Enyin o ri ogo Re na.

4. Fun nyin ni Oluwa,
Pese ile didan,
Ko si ‘kanu nibe
Kik ‘yo l’o kun ‘be;
Enyin mimo bere si ‘yo,
E fere gb’ ohun Angel na.

(Visited 286 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you