YBH 132

ENYIN t’e f’oluwa

1. ENYIN t’e f’oluwa,
T’o mo ‘pa Re, e wa,
E dapo n.isokan,
Lati yin ore Re;
F’orun at’aiye, e kede
Oruko oludande yin.

2. O f’ite Re loke,
At’ogo Re sile,
O f’ife sokale,
O sokun, o si ku;
Iya t’ O je, tani le wi,
Lati gb’okan wa lowo ‘ku?

3. O fo ‘boli: O nde
N’isegun lor’iku;
O k’awon ota Re
T’O segun lat’ibe:
O si l’awon orun koja
N’isegun s’ite Olorun.

4. O fere pada wa, –
Keke Re ki y’o pe, –
Lati m’omo Re lo
Si ile ailopin:
Nibe l’ao ri l’ojukoju,
L’ao ko isegun ore Re.

(Visited 281 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you