1. ISE ‘gbala pari,
Jesu ti ba ‘ku ja,
O se agbara iboji,
O ti di asegun.
2. Ileri t’O ti se,
F’awon omo ehin Re,
Bi Olorun Alagbara,
O f’otito re han.
3. Lehin ajinde Re,
O tun d’ara nla kan,
Eyi t’enikan ko se ri,
T’o bukun ola Re.
4. Ara nla na nip e,
O goke re orun,
Laisi iye lais’akaso
O lo lofurufu.
5. Awon om’ehin Re,
Kanu fun lilo Re,
Pelu ife O so fun won,
Pe On yio pada wa.
6. Gba t’O ba npada bo,
Pel’agbara nla ni,
Yio si m’awon ti se tire,
Goke to Baba Re.
7. Jo masai ka mi kun,
Awon ti se ti Re,
Ki nle wa pelu Re titi,
N’ijoba ailopin.
(Visited 226 times, 1 visits today)