1. IFE orun alailegbe,
Ayo orun sokale:
Fi okan wa se ‘bugbe Re,
Se asetan anu Re;
Jesu, iwo ni alanu,
Iwo l’onibu ife,
Figbala Re be wa wo,
M’okan eru wa duro.
2. Wa,Olodumare gba wa,
Fun wa l’ore-ofe Re,
Lojiji ni k’O pada wa,
Ma si fi wa sile mo;
Iwo l’a o ma yin titi,
Bi nwon ti nse ni orun,
Iyin wa ki yi-o l’opin,
A o s’ogo n’nu ‘fe Re.
3. Sasepe awa eda Re,
Je ka wa lailabawon;
K’a ri titobi ‘gbala Re,
Li aritan ninu Re.
Mu wa lat’ogo de ogo
Titi de ibugbe wa:
Titi awa o fi wole,
N’iyanu, ife, iyin.
(Visited 1,119 times, 1 visits today)