YBH 136

GBOGBO aiye, gbe jesu ga

1. GBOGBO aiye, gbe jesu ga,
Angeli’, e wole fun:
E mu ade Oba Re wa,
Se l’Oba awon oba.

2. E se l’Oba, enyin Martir’
Ti nkepe n’ ite Re;
Gbe gbongbo-igi Jesse ga,
Se l’ Oba awon oba.

3. Enyin iru-omo Israel’,
Ti a ti rapada;
E ki Enit’ o gba nyin la.
Se l’ Oba awon oba.

4. Gbogbo enia elese,
Ranti ‘banuje nyin;
E te ‘kogun nyin s’ ese Re,
Se l’ Oba awon oba.

5. Ki gbogbo orile-ede,
Ni gbogbo agbaiye;
Ki nwon ki “Kabiyesi,”
Se l’ Oba awon oba.

6. A ba le pel’ awon t’ orun,
Lati ma juba Re;
K’ a ba le jo jumo korin,
Se l’ Oba awon oba.

(Visited 9,370 times, 29 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you