1. ENDE, korin Mose
Ati t’ Odagutan;
Ji, gbogbo okan at’ ahon ,
K’ e yin Olugbala.
2. Korin ife ‘ku Re;
At’ ipa ‘dide Re:
Korin b’ O ti mbebe loke
F’ ese awon t’ O ru.
3. Korin l’ ona orun,
Elese t’ a gbala;
Korin l’ ayo l’ ojojumo,
Ninu Krist’ Oba lailai.
4. A fere gbo k’ O pe, –
“Omo ‘bukun, e wa;”
Laipe y’o pew a lo nihin
Si ile wa lailai.
5. Nibe l’ahon wa y’o
Wi ‘yin Re ailopin;
Ao si ko orin ti mose
Ati t’Odagutan.
(Visited 726 times, 1 visits today)