1. GB’ opo duru pelu ohun
Nwon nkorin iyin loke;
Jesu joba, orun si yo;
Olorun ife joba;
Wo, O joko lori ite;
Jesu nikan job’aiye.
2. Jesu, ‘wo t’ogo Re bu ‘yi
Kun ohun gbogbo loke:
Erin Re mu k’oju awon
Emi mimo tire ya:
Gbat’a ro iru ‘fe Tire,
A mo pe ti orun ni.
3. Oba ogo joba lailai:
Ade ailopin n’Tire:
Ko s’ohun t’o le ya awon
Tire lara ife Re:
Nwon j’enit’ore-ofe Re
Yan lati ri oju Re.
4. Olugbala yara k’O wa:
Mu k’ojo ogo na de,
Nigbat’aiye ati orun,
Y’o koja n’iro ‘pe nla:
‘Gbana l’ao fi duru korin,
“Ogo, ogo f’Oba wa.”
(Visited 202 times, 1 visits today)