1. “MO mo p’Oludande mi mbe;”
Itunu nla l’eyi fun mi!
O mbe, Enit’ o ku lekan;
O mbe, Ori iye mi lai.
2. O mbe, lati ma bukun mi,
O si mbebe fun mi loke;
O mbe, lati ji mi n’boji,
Lati gba mi la titi lai.
3. O mbe, Ore korikosun.
Ti y’o pa mi mo de opinl;
O mbe, emi o ma korin,
Woli, Alufa, Oba mi.
4. O mbe, lati pese aye,
Y’o si mu mi de ‘be l’ayo;
O mbe, ogo l’ oruko Re;
Jesu, okanna titi lai.
5. O mbe, mo bo low’ aniyan;
O mbe, mo bo lowo ewu;
A! ayo l’ oro yi fun mi,
“Mo mo p’ Oludande mi mbe!”
(Visited 3,488 times, 8 visits today)