1. SO itan kanna fun mi,
T’ ohun ni t’ a ko ri;
Ti Jesu on ogo Re,
Ti Jesu En ‘ ife,
So itan kanna fun mi,
B’ o ba ti so f’ ewe,
‘Tor’ alailera l’ emi,
Emi ko si n’ n’ okun.
2. So ‘tan na fun mi pele,
Ki o ba le ye mi;
T’ irapada iyanu,
T’ etutu fun ese;
So fun mi nigbagbogbo,
‘Tori nko pe gbagbe;
O ye ori mi ti lo,
Bi iri owuro.
3. So ‘tan na fun mi jeje,
Li ohun otito:
Ranti p’ elese l’ emi,
Ti Jesu wa gba la.
So fun mi nigbakugba,
Bi iwo ba fe se
Olutunu mi n’ igba
Ojo ibi ba de.
4. So itan kanna fun mi,
Igba ti o ba ri
Pe ogo aiye wa yi
Fe gba mi li aya:
‘Gba ogo oke orun,
Ba si nfarahan mi,
So ‘tan kanna fun mi pe
Krist’ mu o l’ ara le.
(Visited 249 times, 1 visits today)