1. OLUWA, y’o ti pe to
T’ Iwo o tun pada;
Are fere mu wa tan,
Bi a ti nw’ ona Re;
Oluwa, y’o ti pe to
T’ a o ma reti Re?
Opo ni ko gbagbo mo
Pe ‘Wo o tun pada.
2. Oluwa y’o ti pe to
T’ Iwo o kesi wa?
Ti awa, ti nreti Re
Yio ri O l’ ayo?
Ji, wundia ti o sun,
Lo kede bibo Re,
Ki gbogbo awon t’ o sun
Le mo pe O mbo wa.
3. Dide, tan fitila re,
Gbe ewu mimo wo,
Mura lati pade Re,
‘Tori On fere de.
Oluwa, y’o ti pe to
T’ Iwo o tun pada?
Ma je ki are mu wa
Tit’ a o fi ri O.
(Visited 459 times, 1 visits today)