YBH 144

JI, apa Olorun, k’ o ji

1. JI, apa Olorun, k’ o ji,
Gbe ‘pa Re wo, mi or’ ile;
Ni sisin Re, je k’ aiye ri
Isegun ise anu Re.

2. T’ ite Re wi fun keferi,
“Emi Jehofa Olorun.”
Ohun Re y’o d’ ere won ru
Yio wo pepe won lu ‘le.

3. Ma je k’ a ta ‘je sile mo,
Ebo asan fun enia;
Si okan gbogbo ni k’ a lo
Eje ti oti iha yo.

4. K’ igb’ ojurere Sion de
K’ a m’ eya Israel wa ‘le;
N’ iyanu k’ a f’ oju wa ri
Keferi, Ju, l’ agbo Jesu.

5. Olodumare, lo ‘fe Re,
L’or’ oruko ile gbogbo;
Ki gbogb’ ota wole fun O,
Ki nwon gba Jesu l’ Oluwa.

(Visited 210 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you