1. WO! Oluwa l’ awonsanma,
O mbo l’ ogo’ l’ ola Re.
Enit’ a pa fun elese
Mbo pelu Angeli Re:
Halleluya!
Halleluya! Amin!
2. Gbogbo eda, wa wo Jesu,
Aso ogo l’ a wo fun;
Awon t’ o gan, awon t’ o pa,
T’ o kan mo agbelebu;
Nwon o sokun
Bi nwon ba ri Oluwa.
3. Erekusu, okun, oke,
Orun, aiye, a fo lo,
Awon t’ o ko a da won ru,
Nigbati nwon gb’ ohun Re.
Wa s’ idajo,
Wa s’ idajo, wa kalo!
4. Idasile t’ a ti nreti,
Opo ewa l’ a fi han!
Awon ti a gan pelu Re
Pade Re loke lohun.
Halleluya!
Ojo Olugbala de.
(Visited 489 times, 1 visits today)