1. OLORUN Olurapada,
Mo ri ‘se mi nin’ oro Re,
Ninu ‘gbe aiye Re nihin,
Ofin f’ ara han gedegbe.
2. Iru otito on ‘tara
Iru ‘wa to jo ti Baba
Iru ‘fe ati ‘nu tutu
Gbogbo won iba je temi.
3. Oke ati oru dudu
Nwon njeri si adura Re
‘Danwo ija isegun Re
Gbogbo won ni aginju mo.
4. K’ iwo ma je awoko mi,
Se mi l’ aworan Re nihin:
Gbana Olorun idajo
Y’o ka mi k’ omo ehin Re.
(Visited 155 times, 1 visits today)