YBH 147

GBA t’ Olugbala w’ aiye

1. GBA t’ Olugbala w’ aiye,
Anu j’ oba l’ okan Re,
O nfi ibakedun han
K’ O si gan enikeni.

2. Afoju Aro y’ Ika,
Aditi at’ abirun,
Ko seni ti ko sai ri
Iwosan gba ni ofe.

3. O s’ adete di mimo
O f’ egbegberun l’ onje
O d’ afefe on iji
O si ji oku dide.

4. Baba fun mi n’ ibukun
Ebi npa mi mo saisan,
Je kin ma gbe ‘waju Re,
Sin mi lo s’ ile orun.

5. Fi ife ti Re han mi,
Fun mi l’ ore ofe Re;
Wo mi emi o si san
Fi ibukun Re fun mi.

(Visited 265 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you