YBH 149

KRIST’ ki ‘joba Re de

1. KRIST’ ki ‘joba Re de,
Ki ase Re bere;
F’ opa-rin Re fo
Gbogbo ipa ese.

2. Ijoba ife da,
Ati t’ Alafia?
Gbawo ni irira
Yio tan bi t’orun?

3. Akoko na ha da,
T’ ote yio pari,
Ika at’ ireje,
Pelu ifekufe?

4. Oluwa joo, dide,
Wa n’nu agbara Re;
Fi ayo fun awa
Ti o nsaferi Re.

5. Eda ngan ooko Re,
‘Koko nje agbo Re;
Iwa ‘tiju pupo
Nfihan pe ‘fe tutu.

6. Ookun bole sibe,
Ni ile keferi:
Dide ‘Rawo ooro,
Dide, mase wo mo. Amin.

(Visited 6,626 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you