1. DIDE, yin Oluwa,
Enyin, ayanfe Re;
E f’ okan ati ohun yin,
N’ iduro, yin l’ ogo.
2. O rekoja iyin,
O ga fun ibukun,
Tani le sai fi eru yin?
Sai gb’ oruko Re ga?
3. A ba le ri ina
Lat’ ori pepe Re,
K’ o kan ete at’ okan wa
Fun ironu t’ orun.
4. Olorun n’ipa wa
Igbala Re ti wa,
E je k’ a kede ife t’o
Ra wa nipa Jesu.
5. Dide, yin Oluwa,
Wole n’ iwaju Re,
Yin oruko Re t’o l’ ogo,
Titi aiyeraiye.
(Visited 1,919 times, 1 visits today)