1. ENYIN iran Adam,
Da ohun orin po,
Mo t’ orun at’ aiye,
Lati yin Eleda;
Enyin ogun angel’ didan
E le ‘rin n’ile imole.
2. Iwo orun didan,
At’ osupa oru,
E pelu irawo,
Ran ‘yin Olorun nyin;
F’ ipa Re han, enyin ojo
Ati sanma ti ngba l’ oke.
3. Aiye ti ndan loke,
Nwon duro n’ ipo won,
Awon t’ o si nsi ‘po,
Nipa ase Re ni;
Oro Re l’o pen won jade
Lati yin Oluwa l’ ogo.
4. K’ oril’-ede beru
Oba t’ o je loke,
O pea won Tire
Lati to ‘fe Re wo;
Nibit’ ile at’ oke nyin,
Awon Tire y’o ma gbe ga.
(Visited 284 times, 1 visits today)