YBH 153

WA, Emi ‘re, ‘Dada orun

1. WA, Emi ‘re, ‘Dada orun
Pelu itunu lat’ oke;
S’ alabo at’ Oluto wa,
To ero at’ isise wa.

2. F’ imole otito han wa,
Mu k’ a mo, k’ a yan ona Re;
F’ eru mimo s’ okan gbogbo:
K’ a ma ba k’ Olorun sile.

3. Mu wa t’ ona mimo
T’ a ni gba ba Olorun gbe;
Mu wa to Krist’ Ona, Iye,
Ma je k’a sako lodo Re.

4. To wa s’ Olorun, ‘Simi wa,
K’ a n’ ibukun pelu Re lai;
To wa s’ orun, k’ a ba le pin
Ekun ayo lailai nibe.

(Visited 296 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you